22. Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là,kì í sì í fi làálàá kún un.
23. Ibi ṣíṣe a máa dùn mọ́ òmùgọ̀,ṣugbọn ìwà ọgbọ́n ni ayọ̀ fún ẹni tí ó mòye.
24. Ohun tí eniyan burúkú ń bẹ̀rù ni yóo dé bá a,ohun tí olódodo ń fẹ́ ni yóo sì rí gbà.
25. Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ,ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae.
26. Bí ọtí kíkan ti rí sí eyín,ati bí èéfín ti rí sí ojú,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí ẹni tí ó bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́.
27. Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn,ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú.
28. Ìrètí olódodo yóo yọrí sí ayọ̀,ṣugbọn ìrètí ẹni ibi yóo jásí òfo.
29. OLUWA jẹ́ agbára fún àwọn tí ọ̀nà wọn tọ́,ṣugbọn ìparun ni fún àwọn oníṣẹ́ ibi.