Ìwé Òwe 10:16-28 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Èrè àwọn olódodo a máa fa ìyè,ṣugbọn èrè àwọn eniyan burúkú a máa fà wọ́n sinu ẹ̀ṣẹ̀.

17. Ẹni tí ó bá gba ìtọ́ni wà ní ọ̀nà ìyè,ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ ìbáwí yóo ṣìnà.

18. Ẹni tí ó di eniyan sinu jẹ́ ẹlẹ́tàn eniyan,ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́, òmùgọ̀ ni.

19. Bí ọ̀rọ̀ bá ti pọ̀ jù, àṣìsọ a máa wọ̀ ọ́,ṣugbọn ẹni tí ó bá kó ẹnu ara rẹ̀ ní ìjánu, ọlọ́gbọ́n ni.

20. Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo dàbí fadaka,ṣugbọn èrò ọkàn eniyan burúkú kò já mọ́ nǹkankan.

21. Ọ̀rọ̀ ẹnu olódodo a máa ṣe ọpọlọpọ eniyan ní anfaani,ṣugbọn òmùgọ̀ eniyan a máa kú nítorí àìgbọ́n.

22. Ibukun OLUWA ní ń mú ni í là,kì í sì í fi làálàá kún un.

23. Ibi ṣíṣe a máa dùn mọ́ òmùgọ̀,ṣugbọn ìwà ọgbọ́n ni ayọ̀ fún ẹni tí ó mòye.

24. Ohun tí eniyan burúkú ń bẹ̀rù ni yóo dé bá a,ohun tí olódodo ń fẹ́ ni yóo sì rí gbà.

25. Nígbà tí ìjì líle bá ń jà, a gbá ẹni ibi lọ,ṣugbọn olódodo a fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí lae.

26. Bí ọtí kíkan ti rí sí eyín,ati bí èéfín ti rí sí ojú,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ rí sí ẹni tí ó bẹ̀ ẹ́ níṣẹ́.

27. Ìbẹ̀rù OLUWA a máa mú kí ẹ̀mí eniyan gùn,ṣugbọn ìgbé ayé eniyan burúkú yóo kúrú.

28. Ìrètí olódodo yóo yọrí sí ayọ̀,ṣugbọn ìrètí ẹni ibi yóo jásí òfo.

Ìwé Òwe 10