Ìwé Òwe 10:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn òwe Solomoni nìwọ̀nyí:Ọlọ́gbọ́n ọmọ á máa mú kí inú baba rẹ̀ dùn,ṣugbọn òmùgọ̀ ọmọ a máa kó ìbànújẹ́ bá ìyá rẹ̀.

2. Ọrọ̀ tí a kójọ lọ́nà èrú kò lérè,ṣugbọn òdodo a máa gba eniyan lọ́wọ́ ikú.

3. OLUWA kì í jẹ́ kí ebi pa olódodo,ṣugbọn ó máa ń da ìfẹ́ ọkàn eniyan burúkú rú.

4. Ìmẹ́lẹ́ máa ń fa òṣì,ṣugbọn ẹni tí ó bá tẹpá mọ́ṣẹ́ yóo di ọlọ́rọ̀.

5. Ọlọ́gbọ́n ní ọmọ tí ó kórè ní àkókò ìkórè,ṣugbọn ọmọ tí ó bá ń sùn lákòókò ìkórèa máa kó ìtìjú báni.

6. Ibukun wà lórí olódodo,ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu,a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.

7. Ayọ̀ ni ìrántí olódodo,ṣugbọn orúkọ eniyan burúkú yóo di ohun ìgbàgbé.

8. Ọlọ́gbọ́n a máa pa òfin mọ́,ṣugbọn òmùgọ̀ onísọkúsọ yóo di ẹni ìparun.

9. Ẹni tí ó bá jẹ́ olóòótọ́ eniyan, yóo máa rìn láìfòyà,ṣugbọn àṣírí alágàbàgebè yóo tú.

10. Ẹni tí bá ń ṣẹ́jú sí ni láti sọ̀rọ̀ èké, a máa dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀,ṣugbọn ẹni tí bá ń báni wí ní gbangba, ń wá alaafia.

11. Ẹnu olódodo dàbí orísun omi ìyè,ṣugbọn eniyan burúkú a máa fi ìwà ìkà sinu,a sì máa sọ̀rọ̀ rere jáde lẹ́nu.

12. Ìkórìíra a máa rú ìjà sókè,ṣugbọn ìfẹ́ a máa fojú fo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dá.

13. Ọ̀rọ̀ ọgbọ́n níí máa ń jáde lẹ́nu ẹni tí ó ní òye,ṣugbọn kùmọ̀ ló yẹ ẹ̀yìn ẹni tí kò gbọ́n.

Ìwé Òwe 10