4. Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn ọkàn òmùgọ̀ wà ní ibi ìgbádùn.
5. Ó dára kí eniyan fetí sí ìbáwí ọlọ́gbọ́n, ju láti máa gbọ́ orin ìyìn àwọn òmùgọ̀ lọ.
6. Bí ẹ̀gún ṣe máa ń ta ninu iná, lábẹ́ ìkòkò, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rín òmùgọ̀ rí. Asán ni èyí pẹlu.
7. Dájúdájú, ìwà ìrẹ́jẹ a máa mú kí ọlọ́gbọ́n eniyan dàbí òmùgọ̀, àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a sì máa ra eniyan níyè.
8. Òpin nǹkan sàn ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ, sùúrù sì dára ju ìwà ìgbéraga lọ.