Ìwé Oníwàásù 3:8-11 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Àkókò láti fi ìfẹ́ hàn wà àkókò láti kórìíra sì wà;àkókò ogun wà, àkókò alaafia sì wà.

9. Kí ni èrè làálàá òṣìṣẹ́?

10. Mo ti mọ ẹrù ńlá tí Ọlọrun dì ru ọmọ eniyan.

11. Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, ní àkókò rẹ̀. Ó fi ayérayé sí ọkàn eniyan, sibẹ, ẹnikẹ́ni kò lè rídìí ohun tí Ọlọrun ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.

Ìwé Oníwàásù 3