15. Ogun ń bẹ lóde; àjàkálẹ̀-àrùn ati ìyàn wà ninu ilé. Ẹni tí ó bá wà lóko yóo kú ikú ogun. Ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn yóo pa ẹni tí ó bá wà ninu ìlú.
16. Bí àwọn kan bá kù, tí wọn sá àsálà, wọn yóo dàbí àdàbà àfonífojì lórí àwọn òkè. Gbogbo wọn yóo máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn olukuluku yóo máa dárò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
17. Ọwọ́ gbogbo wọ́n yóo rọ; orúnkún wọn kò ní lágbára.
18. Wọn óo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ìpayà óo sì bá wọn. Ojú óo ti gbogbo wọn; gbogbo wọn óo sì di apárí.
19. Wọ́n óo fọ́n fadaka wọn dà sílẹ̀ láàrin ìgboro. Wúrà wọn yóo sì dàbí ohun àìmọ́. Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA. Kò ní lè tẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní lè jẹ ẹ́ yó. Nítorí pé wúrà ati fadaka ló mú wọn dẹ́ṣẹ̀.
20. Wọ́n ń lo ohun ọ̀ṣọ́ wọn dáradára fún ògo asán; òun ni wọ́n fi ń ṣe àwọn ère ati oriṣa wọn, àwọn ohun ìríra tí wọn ń bọ. Nítorí náà, OLUWA óo sọ wọ́n di ohun àìmọ́ fún wọn.