Isikiẹli 6:12-14 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa àwọn tí wọ́n wà lókèèrè; idà yóo pa àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ìyàn yóo sì pa àwọn yòókù tí ogun ati àjàkálẹ̀-àrùn bá dá sí. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn patapata.

13. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí òkú wọn bá sùn lọ káàkiri láàrin àwọn ère oriṣa wọn yíká pẹpẹ ìrúbọ wọn, ní gbogbo ibi ìrúbọ ati lórí gbogbo òkè ńlá, lábẹ́ gbogbo igi tútù ati gbogbo igi oaku eléwé tútù; ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí àwọn oriṣa wọn.

14. Ọwọ́ mi óo tẹ̀ wọ́n; n óo sọ ilẹ̀ wọn di ahoro ati òkítì àlàpà, ní gbogbo ibùgbé wọn, láti ibi aṣálẹ̀ títí dé Ribila. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”

Isikiẹli 6