15. Èyí tí ó kù lára ilẹ̀ náà tí ìbú rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbaata (5,000) igbọnwọ (kilomita 2½), tí òòró rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), yóo wà fún lílò àwọn ará ìlú, fún ibùgbé ati ilẹ̀ tí ó yí ìlú ká. Láàrin rẹ̀ ni ìlú yóo wà.
16. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà yóo gùn ní ẹgbaa meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (4,500) igbọnwọ (mita 2,250), ati ti ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati ti àríwá ati ti gúsù.
17. Ilẹ̀ pápá yóo sì wà ní ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ìlú náà, ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan yóo gùn ní igba ó lé aadọta (250) igbọnwọ (mita 125).
18. Ilẹ̀ tí ó kù lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà yóo jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, ati ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5) ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn. Yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ mímọ́ náà. Èso ilẹ̀ náà yóo jẹ́ oúnjẹ fún àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ninu ìlú.