11. Yóo jẹ́ ti àwọn alufaa tí a yà sọ́tọ̀, àwọn ọmọ Sadoku tí wọ́n pa òfin mi mọ́, tí wọn kò sì ṣáko lọ bí àwọn ọmọ Lefi, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ.
12. Lọ́tọ̀ ni a óo fún wọn ní ilẹ̀ tiwọn. Yóo jẹ́ ìpín tiwọn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA, ilẹ̀ mímọ́ jùlọ; yóo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ ti àwọn ọmọ Lefi.
13. Àwọn ọmọ Lefi yóo ní ìpínlẹ̀ tiwọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilẹ̀ tí a pín fún àwọn alufaa, òòró rẹ̀ yóo jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaata (25,000) igbọnwọ (kilomita 12½), ìbú rẹ̀ yóo sì jẹ́ ẹgbaarun (10,000) igbọnwọ (kilomita 5).
14. Wọn kò gbọdọ̀ tà ninu rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi yáwó, wọn kò sì gbọdọ̀ fún ẹlòmíràn lára ilẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ yìí; nítorí pé mímọ́ ni, ti OLUWA sì ni.