Isikiẹli 44:14-16 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Sibẹsibẹ, n óo yàn wọ́n láti máa tọ́jú tẹmpili ati láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ ní ṣíṣe ninu rẹ̀.

15. “Ṣugbọn àwọn alufaa ọmọ Lefi láti ìran Sadoku, tí wọn ń tọ́jú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, àwọn ni yóo máa lọ sí ibi pẹpẹ mi láti rúbọ sí mi. Àwọn ni wọn óo máa fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

16. Àwọn ni wọn óo máa wọ ibi mímọ́ mi, wọn óo máa lọ sí ibi tabili mi, tí wọn óo máa ṣiṣẹ́ iranṣẹ, wọn óo sì máa pa àṣẹ mi mọ́.

Isikiẹli 44