Isikiẹli 43:13 BIBELI MIMỌ (BM)

Bí ìwọ̀n pẹpẹ náà ti rí nìyí; irú ọ̀pá kan náà tí ó jẹ́ igbọnwọ kan ati ìbú àtẹ́lẹwọ́ (ìdajì mita kan) kan ni ó fi wọ̀n ọ́n. Pèpéle pẹpẹ náà yóo ga ní igbọnwọ kan, yóo fẹ̀ ní igbọnwọ kan. Etí rẹ̀ yíká fẹ̀ ní ìka kan (idamẹrin mita kan).

Isikiẹli 43

Isikiẹli 43:6-18