Isikiẹli 38:6-8 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Gomeri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati Beti Togama láti òpin ilẹ̀ ìhà àríwá ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀; bẹ́ẹ̀ náà ni ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, wọ́n wà pẹlu rẹ̀.

7. Dira ogun, kí o sì wà ní ìmúrasílẹ̀, ìwọ ati gbogbo eniyan tí wọ́n pé yí ọ ká, kí o jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ fún wọn.

8. Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́ a óo ko yín jọ. Ní ọdún mélòó kan sí i, ẹ óo gbógun ti ilẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ sípò lẹ́yìn ìparun ogun, orílẹ̀-èdè tí a ṣà jọ láti ààrin ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè mìíràn sórí àwọn òkè ńláńlá Israẹli, ilẹ̀ tí ó ti wà ní ahoro fún ọpọlọpọ ọdún. Láti inú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ni a ti ṣa àwọn eniyan rẹ̀ jọ; nisinsinyii, gbogbo wọn wà láìléwu.

Isikiẹli 38