Isikiẹli 37:15-22 BIBELI MIMỌ (BM)

15. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

16. “Ìwọ ọmọ eniyan, mú igi kan kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Igi Juda ati àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’ Mú igi mìíràn kí o kọ sí ara rẹ̀ pé, ‘Ti Josẹfu, (igi Efuraimu) ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀.’

17. Fi ẹnu wọn ko ara wọn, kí wọ́n di igi kan lọ́wọ́ rẹ.

18. Bí àwọn eniyan rẹ bá bi ọ́ pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí ò ń ṣe yìí?

19. Wí fún wọn pé èmi OLUWA Ọlọrun ní: ‘N óo mú igi Josẹfu ati àwọn ìdílé Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, n óo fi ẹnu rẹ̀ ko ẹnu igi Juda; n óo sọ wọ́n di igi kan, wọn yóo sì di ọ̀kan lọ́wọ́ mi.’

20. “Mú àwọn igi tí o kọ nǹkan sí lára lọ́wọ́, lójú wọn,

21. kí o sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ wò ó! N óo kó àwọn ọmọ Israẹli jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà, n óo kó wọn jọ láti ibi gbogbo wá sí ilẹ̀ wọn.

22. N óo sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè kan ní orí òkè Israẹli, ọba kanṣoṣo ni yóo sì jẹ lé gbogbo wọn lórí. Wọn kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè meji mọ́; wọn kò ní pín ara wọn sí ìjọba meji mọ́.

Isikiẹli 37