4. bí ẹnìkan bá gbọ́ ìró fèrè náà, ṣugbọn tí kò bá bìkítà fún ogun àgbọ́-tẹ́lẹ̀ yìí, bí ogun bá pa á orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà.
5. Ó gbọ́ ìró fèrè ṣugbọn kò bìkítà, nítorí náà orí ara rẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóo wà. Bí ó bá gbọ́ ìkìlọ̀ ni, kì bá gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là.
6. Ṣugbọn bí olùṣọ́ bá rí i pé ogun ń bọ̀, tí kò bá fọn fèrè kí ó kìlọ̀ fún àwọn eniyan; bí ogun bá pa ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹni tí ogun pa yóo kú ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn èmi OLUWA óo bèèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ olùṣọ́ náà.
7. “Ọmọ eniyan, ìwọ ni mo yàn ní olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nígbàkúùgbà tí o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́nu mi, o níláti bá mi kìlọ̀ fún wọn.