Isikiẹli 17:8-14 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Idì yìí bá hú u níbi tí wọ́n gbìn ín sí, ó lọ gbìn ín sí ilẹ̀ kan tí ó lọ́ràá lẹ́bàá odò, kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so èso, kí ó sì di àjàrà ńlá tí ó níyì.

9. “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní kí o bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé àjàrà yìí yóo ṣe dáradára? Ṣé idì ti àkọ́kọ́ kò ní fa gbòǹgbò rẹ̀ tu, kí ó gé ẹ̀ka rẹ̀, kí àwọn ewé rẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ sì rọ?’ Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò alágbára tabi ọ̀pọ̀ eniyan, láti fà á tu tigbòǹgbò tigbòǹgbò.

10. Nígbà tí wọ́n bá tún un gbìn ǹjẹ́ yóo yè? Ṣé kò ní gbẹ patapata nígbà tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn bá fẹ́ lù ú? Yóo gbẹ níbi tí wọ́n gbìn ín sí.”

11. Lẹ́yìn náà, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

12. “Bi àwọn ọlọ̀tẹ̀ wọnyi pé, ṣé wọn kò mọ ìtumọ̀ òwe wọnyi ni? Sọ pé ọba Babiloni wá sí Jerusalẹmu, ó sì kó ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ní Babiloni.

13. Ó mú ọ̀kan ninu àwọn ìdílé ọba, ó bá a dá majẹmu, ó sì mú kí ó búra. Ó ti kọ́ kó gbogbo àwọn eniyan pataki pataki ilẹ̀ náà lọ,

14. kí ilẹ̀ náà lè di ìrẹ̀sílẹ̀, kí wọ́n má sì lè gbérí mọ́, ṣugbọn kí ilẹ̀ náà lè máa ní ìtẹ̀síwájú, níwọ̀n ìgbà tí ó bá pa majẹmu ọba Babiloni mọ́.

Isikiẹli 17