1. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
2. “Ìwọ ọmọ eniyan, pa àlọ́ kan kí o sì fi òwe bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀.
3. Wí fún wọn pé, OLUWA Ọlọrun ní idì ńlá kan wá sí Lẹbanoni, apá rẹ̀ tóbi, ìrù rẹ̀ sì gùn, ó sì ní ìyẹ́ aláràbarà. Ó bá bà lé ṣóńṣó orí igi kedari kan,
4. ó ṣẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ lórí, ó gbé e lọ sí ilẹ̀ àwọn oníṣòwò; ó fi sí ìlú àwọn tí ń ta ọjà.