10. àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà á dojúbolẹ̀ níwájú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wọn a júbà ẹni tí ó wà láàyè lae ati laelae, wọn a fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wọ́n a máa wí pé,
11. “Oluwa Ọlọrun wa, ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ògo, ati ọlá ati agbára.Nítorí ìwọ ni ó dá ohun gbogbo,ati pé nípa ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà,nípa rẹ ni a sì ṣe dá wọn.”