Ìfihàn 4:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn èyí mo tún rí ìran mìíran. Mo rí ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run. Mo wá gbọ́ ohùn kan bíi ti àkọ́kọ́.Tí ó dàbí ìgbà tí kàkàkí bá ń dún, tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní, “Gòkè wá níhìn-ín. N óo fi àwọn ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.”

2. Lẹsẹkẹsẹ ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo bá rí ìtẹ́ kan ní ọ̀run. Ẹnìkan jókòó lórí rẹ̀.

3. Ojú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà dàbí òkúta iyebíye oríṣìí meji. Òṣùmàrè yí ìtẹ́ náà ká, ó ń tan ìmọ́lẹ̀ bí òkúta iyebíye.

4. Àwọn ìtẹ́ mẹrinlelogun ni wọ́n yí ìtẹ́ náà ká. Àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun sì jókòó lórí ìtẹ́ mẹrinlelogun náà. Wọ́n wọ aṣọ funfun, wọ́n dé adé wúrà.

Ìfihàn 4