21. Ọ̀kan ninu àwọn angẹli alágbára bá gbé òkúta tí ó tóbi bí ọlọ ògì, ó jù ú sinu òkun, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni a óo fi tagbára-tagbára sọ Babiloni ìlú ńlá náà mọ́lẹ̀ tí a kò ní rí i mọ́.
22. A kò tún ní gbọ́ ohùn fèrè ati ti àwọn olórin tabi ti ohùn ìlù ati ti ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ ninu rẹ mọ́. A kò ní tún rí àwọn oníṣọ̀nà fún iṣẹ́ ọnà kan ninu rẹ mọ́. A kò ní gbọ́ ìró ọlọ ninu rẹ mọ́.
23. Iná àtùpà kan kò ní tàn ninu rẹ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́. Nígbà kan rí àwọn oníṣòwò rẹ ni àwọn gbajúmọ̀ ninu ayé. O fi ìwà àjẹ́ tan gbogbo orílẹ̀-èdè jẹ.”