Ìfihàn 1:3-6 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ẹni tí ó bá ń ka ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ati àwọn tí ó bá ń gbọ́, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tí a kọ, ṣe oríire. Nítorí àkókò tí yóo ṣẹlẹ̀ súnmọ́ tòsí.

4. Èmi Johanu ni mo ranṣẹ sí ìjọ meje tí ó wà ní agbègbè Esia.Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia wà pẹlu yín láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti wà, tí ó ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí meje tí wọ́n wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀;

5. ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé.Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.

6. Ó sọ wá di ìjọba, ati alufaa Ọlọrun Baba rẹ̀. Tirẹ̀ ni ògo ati agbára lae ati laelae. Amin.

Ìfihàn 1