7. “Bí ẹ̀yin alufaa ti ń pọ̀ sí i, ni ẹ̀ṣẹ̀ yín náà ń pọ̀ sí i, n óo yí ògo wọn pada sí ìtìjú.
8. Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi wá oúnjẹ fún ara yín, ẹ sì ń mú kí wọ́n máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀
9. Ìyà kan náà ni ẹ̀yin alufaa ati àwọn eniyan yóo jẹ, n óo jẹ yín níyà nítorí ìwà burúkú yín, n óo sì gbẹ̀san lára yín nítorí ìṣe yín.
10. Ẹ óo máa jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó; Ẹ óo máa ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ṣugbọn ẹ kò ní pọ̀ sí i; nítorí ẹ ti kọ èmi Ọlọrun sílẹ̀ ẹ sì yipada sí ìwà ìbọkúbọ.”
11. OLUWA ní, “Ọtí waini ati waini tuntun ti ra àwọn eniyan mi níyè.
12. Wọ́n ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ igi gbígbẹ́, ọ̀pá wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wọn. Ẹ̀mí àgbèrè ẹ̀sìn ti mú wọn ṣáko, wọ́n ti kọ Ọlọrun wọn sílẹ̀ láti máa bọ ìbọkúbọ.