Hosia 4:17-19 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ìbọ̀rìṣà ti wọ Efuraimu lẹ́wù, ẹ fi wọ́n sílẹ̀.

18. Ẹgbẹ́ ọ̀mùtí ni wọ́n, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àgbèrè, ìtìjú yá wọn lára ju ògo lọ.

19. Afẹ́fẹ́ yóo gbá wọn lọ, ojú ìsìn ìbọ̀rìṣà wọn yóo sì tì wọ́n.

Hosia 4