16. Israẹli ń ṣe agídí bí ọ̀dọ́ mààlúù tí ó ya olóríkunkun; ṣe OLUWA lè máa bọ́ wọn bí aguntan nisinsinyii lórí pápá tí ó tẹ́jú.
17. Ìbọ̀rìṣà ti wọ Efuraimu lẹ́wù, ẹ fi wọ́n sílẹ̀.
18. Ẹgbẹ́ ọ̀mùtí ni wọ́n, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àgbèrè, ìtìjú yá wọn lára ju ògo lọ.