Hosia 4:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; OLUWA fi ẹ̀sùn kan gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli pé, “Kò sí òtítọ́, tabi àánú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀ Ọlọrun ní ilẹ̀ náà,

2. àfi ìbúra èké ati irọ́ pípa; ìpànìyàn, olè jíjà ati àgbèrè ni ó pọ̀ láàrin wọn. Wọ́n ń yẹ àdéhùn, wọ́n ń paniyan léraléra.

3. Nítorí náà, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀ ń jìyà, àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn ẹja sì ń ṣègbé.”

Hosia 4