Hosia 1:7-11 BIBELI MIMỌ (BM)

7. n kò sì ní dáríjì wọ́n mọ́, ṣugbọn n óo fẹ́ràn ilé Juda, n óo sì ṣàánú wọn, èmi OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n là, láìlo ọfà ati ọrun, idà tabi ogun, tabi ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin.”

8. Lẹ́yìn tí Gomeri gba ọmú lẹ́nu ‘Kò sí Àánú’ ó tún lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan.

9. OLUWA tún sọ fún Hosia pé: “Sọ ọmọ náà ní ‘Kì í ṣe Eniyan Mi’, nítorí pé ẹ̀yin ọmọ Israẹli kì í ṣe eniyan mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọrun yín.”

10. Àwọn ọmọ Israẹli yóo pọ̀ sí i bí iyanrìn etí òkun tí kò ṣe é wọ̀n, tí kò sì ṣe é kà. Níbi tí a ti sọ fún wọn pé, “Kì í ṣe eniyan mi”, níbẹ̀ ni a óo ti pè wọ́n ní, “ọmọ Ọlọrun Alààyè.”

11. A óo kó àwọn eniyan Israẹli ati ti Juda papọ̀, wọn óo yan olórí kanṣoṣo fún ara wọn; wọn óo sì máa ti ibẹ̀ jáde wá. Dájúdájú, ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesireeli yóo jẹ́.

Hosia 1