Heberu 8:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Kókó ohun tí à ń sọ nìyí, pé a ní irú Olórí Alufaa báyìí, ẹni tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ ọlá ńlá ní ọ̀run.

2. Òun yìí ni òjíṣẹ́ ní ilé ìsìn tí ó mọ́ jùlọ tíí ṣe àgọ́ tòótọ́, tí Oluwa fúnrarẹ̀ kọ́, kì í ṣe èyí tí eniyan kọ́.

Heberu 8