15. Bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,ẹ má ṣe agídí gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ọ̀tẹ̀.”
16. Mò ń bèèrè, àwọn ta ni ó gbọ́ tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀? Ṣebí gbogbo àwọn tí wọ́n bá Mose jáde kúrò ní Ijipti ni.
17. Àwọn ta ni Ọlọrun bínú sí ní ogoji ọdún? Ṣebí àwọn tí ó ṣẹ̀ ni, tí òkú wọn wà káàkiri ní aṣálẹ̀.
18. Àwọn ta ni ó búra pé wọn kò ní wọ inú ìsinmi òun? Ṣebí àwọn aláìgbọràn ni.
19. A rí i pé wọn kò lè wọ inú ìsinmi yìí nítorí wọn kò gbàgbọ́.