Heberu 10:3-5 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ṣugbọn àwọn ẹbọ wọnyi ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí lọdọọdun,

4. nítorí ẹ̀jẹ̀ mààlúù ati ti ewúrẹ́ kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ.

5. Nítorí náà, nígbà tí Kristi wọ inú ayé wá, ó sọ fún Ọlọrun pé,“Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ ni o fẹ́,ṣugbọn o ti ṣe ètò ara kan fún mi.

Heberu 10