5. Nítorí náà, nisinsinyii, ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín:
6. Ohun ọ̀gbìn pupọ ni ẹ gbìn, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ kórè; ẹ jẹun, ṣugbọn ẹ kò yó; ẹ mu, ṣugbọn kò tẹ yín lọ́rùn; ẹ wọṣọ, sibẹ òtútù tún ń mu yín. Àwọn tí wọn ń gba owó iṣẹ́ wọn, inú ajádìí-àpò ni wọ́n ń gbà á sí.
7. Ẹ kíyèsí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ si yín. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
8. Ẹ lọ sórí àwọn òkè, kí ẹ gé igi ìrólé láti kọ́ ilé náà, kí inú mi lè dùn sí i, kí n sì lè farahàn ninu ògo mi. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí.
9. “Ẹ̀ ń retí ọ̀pọ̀ ìkórè, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí; nígbà tí ẹ sì mú díẹ̀ náà wálé, èmi á gbọ̀n ọ́n dànù. Mò ń bi yín, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ó fà á? Ìdí rẹ̀ ni pé, ẹ fi ilé mi sílẹ̀ ní òkítì àlàpà, olukuluku sì múra sí kíkọ́ ilé tirẹ̀.
10. Ìdí nìyí tí ìrì kò fi sẹ̀ láti òkè ọ̀run wá, tí ilẹ̀ kò sì fi so èso bí ó ti yẹ.