1. Adura tí wolii Habakuku kọ lórin nìyí:
2. OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ,mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́;tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa;sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ.
3. OLUWA wá láti Temani,Ẹni Mímọ́ sì wá láti òkè Parani.Ògo rẹ̀ bo ojú ọ̀run,gbogbo ayé sì kún fún ìyìn rẹ̀.
4. Dídán rẹ̀ dàbí ọ̀sán gangan,ìtànṣán ń ti ọwọ́ rẹ̀ jáde;níbẹ̀ ni ó fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.
5. Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀,ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí.
6. Ó dúró, ó wọn ayé;Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì;àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká,àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀.Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀.