17. Kì í ṣe ẹ̀bùn ni mò ń wá, ṣugbọn mò ń wá ọpọlọpọ èso fún anfaani yín.
18. Ìwé ẹ̀rí nìyí fún ohun gbogbo tí ẹ fún mi, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù. Mo ní ànító nígbà tí mo rí ohun tí ẹ fi rán Epafiroditu sí mi gbà. Ó dàbí òróró olóòórùn dídùn, bí ẹbọ tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà, tí inú Ọlọrun dùn sí.
19. Ọlọrun mi yóo pèsè fún gbogbo àìní ẹ̀yin náà, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ tí ó lógo nípasẹ̀ Jesu Kristi.
20. Kí ògo kí ó jẹ́ ti Ọlọrun Baba wa lae ati laelae. Amin.
21. Ẹ kí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun tí ó jẹ́ ti Kristi Jesu. Àwọn arakunrin tí ó wà lọ́dọ̀ mi ki yín.
22. Gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun ki yín, pàápàá jùlọ àwọn ti ìdílé Kesari.
23. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu ẹ̀mí yín.