Ẹsita 7:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọba ati Hamani lọ bá Ayaba Ẹsita jẹ àsè.

2. Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń mu ọtí, ọba tún bi Ẹsita pé, “Ẹsita, Ayaba, kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ, a óo ṣe é fún ọ. Kí ni ìbéèrè rẹ, gbogbo rẹ̀ ni yóo sì tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́, àní títí kan ìdajì ìjọba mi.”

Ẹsita 7