Ẹsita 6:7-10 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nítorí náà, ó dá ọba lóhùn pé, “Báyìí ni ó ṣe yẹ kí á dá ẹni tí inú ọba dùn sí lọ́lá:

8. kí wọ́n mú aṣọ ìgúnwà ọba, tí ọba ti wọ̀ rí, ati ẹṣin tí ó ti gùn rí, kí wọ́n sì fi adé ọba dé ẹni náà lórí,

9. kí wọ́n kó wọn fún ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè ọba tí ó ga jùlọ, kí ó fi ṣe ẹni náà lọ́ṣọ̀ọ́, kí ó gbé e gun ẹṣin, kí ó sì fà á káàkiri gbogbo ìlú, kí ó máa kéde pé, ‘Ẹ wo ohun tí ọba ṣe fún ẹni tí inú rẹ̀ dùn sí láti dá a lọ́lá.’ ”

10. Ọba bá sọ fún Hamani pé, “Yára lọ mú aṣọ ìgúnwà, ati ẹṣin náà, kí o sì ṣe bí o ti wí sí Modekai, Juu, tí ó máa ń jókòó sí ẹnu ọ̀nà ààfin.”

Ẹsita 6