Ẹsita 6:13-14 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ó sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i fún Sereṣi, iyawo rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ ati iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí Modekai, ẹni tí o ti bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀ níwájú rẹ̀ bá jẹ́ Juu, o kò ní lè ṣẹgun rẹ̀, òun ni yóo ṣẹgun rẹ.”

14. Bí wọ́n ti ń bá Hamani sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni àwọn ìwẹ̀fà ọba dé láti yára mú un lọ sí ibi àsè Ẹsita.

Ẹsita 6