8. Ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ní àkókò yìí, OLUWA Ọlọrun wa, o ṣàánú wa, o dá díẹ̀ sí ninu wa, à ń gbé ní àìléwu ní ibi mímọ́ rẹ. O jẹ́ kí ara dẹ̀ wá díẹ̀ ní oko ẹrú, o sì ń mú inú wa dùn.
9. Ẹrú ni wá; sibẹ ìwọ Ọlọrun wa kò fi wá sílẹ̀ ninu oko ẹrú, ṣugbọn o fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa, lọ́dọ̀ àwọn ọba Pasia; o sọ wá jí láti kọ́ ilé Ọlọrun wa, láti tún àwọn àlàpà rẹ̀ mọ ati láti mọ odi yí Judia ati Jerusalẹmu ká.
10. “Áà, Ọlọrun wa, kí ni a tún lè wí lẹ́yìn èyí? Nítorí a ti kọ òfin rẹ sílẹ̀,
11. àní, òfin tí o ṣe, tí o fi rán àwọn wolii sí wa pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìríra, pẹlu ìwà ẹ̀gbin àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ náà ti sọ ọ́ di aláìmọ́.