17. Mo rán wọn lọ sọ́dọ̀ Ido, olórí àwọn eniyan ní Kasifia; mo ní kí wọ́n sọ fún Ido ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili pé kí wọ́n fi àwọn eniyan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu ilé Ọlọrun wa ranṣẹ.
18. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, wọ́n fi Ṣerebaya, ọlọ́gbọ́n eniyan kan ranṣẹ sí wa. Ọmọ Israẹli ni, láti inú àwọn ọmọ Mahili, ninu ẹ̀yà Lefi: wọ́n fi ranṣẹ pẹlu àwọn ọmọ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogun.
19. Wọ́n tún rán Haṣabaya, òun ati Jeṣaya ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Merari; pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ wọn. Gbogbo wọn jẹ́ ogún,
20. láì tíì ka igba ó lé ogún (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tí Dafidi ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a kọ orúkọ wọn sinu ìwé.