Ẹsira 2:34-41 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345)

35. Àwọn ọmọ Senaa jẹ́ egbejidinlogun ó lé ọgbọ̀n (3,630)

36. Iye àwọn alufaa tí wọ́n pada dé láti, oko ẹrú wọn nìwọ̀nyí:Àwọn ọmọ Jedaaya láti inú ìdílé Jeṣua jẹ́ ẹẹdẹgbẹrun ó lé mẹtalelaadọrin (973)

37. Àwọn ọmọ Imeri jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mejilelaadọta (1,052)

38. Àwọn ọmọ Paṣuri jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹtadinlaadọta (1,247)

39. Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ẹgbẹrun ó lé mẹtadinlogun (1,017)

40. Iye àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú nìwọ̀nyí:Àwọn ọmọ Jeṣua ati Kadimieli láti inú ìran Hodafaya jẹ́ mẹrinlelaadọrin

41. Àwọn ọmọ Asafu tí wọ́n jẹ́ akọrin ní tẹmpili jẹ́ mejidinlaadoje (128)

Ẹsira 2