26. Àwọn ọmọ Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta ó lé mọkanlelogun (621)
27. Àwọn ọmọ Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122)
28. Àwọn eniyan Bẹtẹli ati Ai jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223)
29. Àwọn ọmọ Nebo jẹ́ mejilelaadọta
30. Àwọn ọmọ Magibiṣi jẹ́ mẹrindinlọgọjọ (156)
31. Àwọn ọmọ Elamu keji jẹ́ ẹgbẹfa ó lé mẹrinlelaadọta (1,254)
32. Àwọn ọmọ Harimu jẹ́ ọọdunrun ó lé ogún (320)
33. Àwọn ọmọ Lodi, Hadidi ati Ono jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹẹdọgbọn (725)
34. Àwọn ọmọ Jẹriko jẹ́ ojilelọọdunrun ó lé marun-un (345)