17. Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹtalelogun (323)
18. Àwọn ọmọ Jora jẹ́ aadọfa ó lé meji (112)
19. Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223)
20. Àwọn ọmọ Gibari jẹ́ marundinlọgọrun-un
21. Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu jẹ́ mẹtalelọgọfa (123)
22. Àwọn eniyan Netofa jẹ́ mẹrindinlọgọta
23. Àwọn eniyan Anatoti jẹ́ mejidinlaadoje (128)
24. Àwọn ọmọ Asimafeti jẹ́ mejilelogoji
25. Àwọn ọmọ Kiriati Jearimu; Kefira ati Beeroti jẹ́ ẹẹdẹgbẹrin ó lé mẹtalelogoji (743)
26. Àwọn ọmọ Rama ati Geba jẹ́ ẹgbẹta ó lé mọkanlelogun (621)
27. Àwọn ọmọ Mikimaṣi jẹ́ mejilelọgọfa (122)
28. Àwọn eniyan Bẹtẹli ati Ai jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223)
29. Àwọn ọmọ Nebo jẹ́ mejilelaadọta