13. Àwọn ọmọ Adonikamu jẹ́ ẹgbẹta ó lé mẹrindinlaadọrin (666)
14. Àwọn ọmọ Bigifai jẹ́ ẹgbaa ó lé mẹrindinlọgọta (2,056)
15. Àwọn ọmọ Adini jẹ́ irinwo ó lé mẹrinlelaadọta (454)
16. Àwọn ọmọ Ateri láti inú ìran Hesekaya jẹ́ mejidinlọgọrun-un
17. Àwọn ọmọ Besai jẹ́ ọọdunrun ó lé mẹtalelogun (323)
18. Àwọn ọmọ Jora jẹ́ aadọfa ó lé meji (112)
19. Àwọn ọmọ Haṣumu jẹ́ igba ó lé mẹtalelogun (223)