8. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ké pè é fún ìrànlọ́wọ́,sibẹsibẹ kò gbọ́ adura mi.
9. Ó to òkúta gbígbẹ́ dí ọ̀nà mi,ó mú kí ọ̀nà mí wọ́.
10. Ó ba dè mí bí ẹranko ìjàkùmọ̀,ó lúgọ bíi kinniun,
11. Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi,ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,ó sì ti sọ mí di alailẹnikan.
12. Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀,ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
13. Ó mú gbogbo ọfàtí ó wà ninu apó rẹ̀ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn.
14. Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́lọ́dọ̀ gbogbo eniyan,ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru.
15. Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́,ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó.
16. Ó fẹnu mi gbolẹ̀,títí yangí fi ká mi léyín;ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku
17. Ọkàn mi kò ní alaafia,mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀.
18. Nítorí náà, mo wí pé,“Ògo mi ti tán,ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.”
19. Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi,ati ìrora ọkàn mi!
20. Mò ń ranti nígbà gbogbo,ọkàn mi sì ń rẹ̀wẹ̀sì.
21. Ṣugbọn mo tún ń ranti nǹkankan,mo sì ní ìrètí.
22. Nítorí pé Ìfẹ́ OLUWA tí kì í yẹ̀ kò nípẹ̀kun,àánú rẹ̀ kò sì lópin;
23. ọ̀tun ni wọ́n láràárọ̀,òtítọ́ rẹ̀ pọ̀.
24. Ọkàn mi wí pé, “OLUWA ni ìpín mi,nítorí náà lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí mi wà.”
25. OLUWA a máa ṣe oore fún àwọn tí wọn dúró dè é,tí wọn sì ń wá ojurere rẹ̀.
26. Ó dára kí eniyan dúró jẹ́ẹ́, de ìgbàlà OLUWA.