Ẹkún Jeremaya 3:61-66 BIBELI MIMỌ (BM)

61. “O ti gbọ́ bí wọn tí ń pẹ̀gàn mi, OLUWA,ati gbogbo ète wọn lórí mi.

62. Gbogbo ọ̀rọ̀ ati èrò àwọn ọ̀tá mi sí mi:ibi ni lojoojumọ.

63. Kíyèsí i, wọn ìbáà jókòó,wọn ìbáà dìde dúró,èmi ni wọ́n máa fi ń kọrin.

64. “O óo san ẹ̀san fún wọn, OLUWA,gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn.

65. Jẹ́ kí ojú inú wọn fọ́,kí ègún rẹ sì wà lórí wọn.

66. Fi ibinu lépa wọn, OLUWA,sì pa wọ́n run láyé yìí.”

Ẹkún Jeremaya 3