59. O ti rí nǹkan burúkú tí wọ́n ṣe sí mi,OLUWA, dá mi láre.
60. O ti rí gbogbo ìgbẹ̀san wọn,ati gbogbo ète wọn lórí mi.
61. “O ti gbọ́ bí wọn tí ń pẹ̀gàn mi, OLUWA,ati gbogbo ète wọn lórí mi.
62. Gbogbo ọ̀rọ̀ ati èrò àwọn ọ̀tá mi sí mi:ibi ni lojoojumọ.
63. Kíyèsí i, wọn ìbáà jókòó,wọn ìbáà dìde dúró,èmi ni wọ́n máa fi ń kọrin.
64. “O óo san ẹ̀san fún wọn, OLUWA,gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn.
65. Jẹ́ kí ojú inú wọn fọ́,kí ègún rẹ sì wà lórí wọn.