40. Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò,kí á tún ọ̀nà wa ṣe,kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA.
41. Ẹ jẹ́ kí á gbé ojú wa sókè,kí á ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun ọ̀run:
42. “A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun,ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá.
43. “O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù,ò ń lépa wa,o sì ń pa wá láì ṣàánú wa.
44. O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ,tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ.
45. O ti sọ wá di ààtànati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan.
46. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára.
47. Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa.
48. Omijé ń dà pòròpòrò lójú mi,nítorí ìparun àwọn eniyan mi.
49. “Omijé yóo máa dà pòròpòrò lójú miláì dáwọ́ dúró, ati láìsinmi.