Ẹkún Jeremaya 3:37-47 BIBELI MIMỌ (BM)

37. Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀,láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i?

38. Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògoni rere ati burúkú ti ń jáde?

39. Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè kan yóo fi máa ráhùnnígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

40. Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò,kí á tún ọ̀nà wa ṣe,kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA.

41. Ẹ jẹ́ kí á gbé ojú wa sókè,kí á ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun ọ̀run:

42. “A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun,ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá.

43. “O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù,ò ń lépa wa,o sì ń pa wá láì ṣàánú wa.

44. O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ,tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ.

45. O ti sọ wá di ààtànati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan.

46. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára.

47. Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa.

Ẹkún Jeremaya 3