11. Ó wọ́ mi kúrò lójú ọ̀nà mi,ó fà mí ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,ó sì ti sọ mí di alailẹnikan.
12. Ó kẹ́ ọfà, ó fa ọrun rẹ̀,ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.
13. Ó mú gbogbo ọfàtí ó wà ninu apó rẹ̀ó ta wọ́n mọ́ mi lọ́kàn.
14. Mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́lọ́dọ̀ gbogbo eniyan,ẹni tí wọ́n fi ń kọrin tọ̀sán-tòru.
15. Ó mú kí ọkàn mi kún fún ìbànújẹ́,ó fún mi ní iwọ mu ní àmuyó.
16. Ó fẹnu mi gbolẹ̀,títí yangí fi ká mi léyín;ó gún mi mọ́lẹ̀ ninu eruku
17. Ọkàn mi kò ní alaafia,mo ti gbàgbé ohun tí ń jẹ́ ayọ̀.
18. Nítorí náà, mo wí pé,“Ògo mi ti tán,ati gbogbo ohun tí mò ń retí lọ́dọ̀ OLUWA.”
19. Ranti ìyà ati ìbànújẹ́ mi,ati ìrora ọkàn mi!