Òrùka aṣọ ìgbàyà yìí ni wọ́n fi dè é mọ́ òrùka ara efodu pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan, kí ó lè sùn lé àmùrè efodu náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.