Ẹkisodu 33:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA tún pe Mose, ó ní, “Dìde kúrò níhìn-ín, ìwọ ati àwọn eniyan tí o kó wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé n óo fún arọmọdọmọ wọn.

2. N óo rán angẹli mi ṣáájú yín, n óo sì lé àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hamori, àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi jáde.

Ẹkisodu 33