11. aládùúgbò náà yóo lọ sí ilé Ọlọrun, yóo sì fi OLUWA ṣẹ̀rí pé òun kọ́ ni òun jí ẹran tí wọn fún òun sìn. Ẹni tí ó fún un ní ẹran sìn yóo faramọ́ ìbúra yìí, kò sì ní gbẹ̀san mọ́.
12. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé wọ́n jí i gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ ni, yóo san ẹ̀san fún ẹni tí ó ni ín.
13. Bí ó bá jẹ́ pé ẹranko burúkú ni ó pa á, bí ó bá ní ohun tí ó lè fi ṣe ẹ̀rí, tí ó sì fi ohun náà han ẹni tí ó ni ẹran náà, kò ní san ẹ̀san ẹran náà pada.
14. “Bí ẹnìkan bá yá ẹran ọ̀sìn kẹ́ran ọ̀sìn lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹran náà bá farapa tabi tí ó kú, tí kò sì sí olówó ẹran náà níbẹ̀, ẹni tí ó yá ẹran náà níláti san án pada.
15. Ṣugbọn bí ẹni tí ó ni ẹran náà bá wà níbẹ̀ nígbà tí ó kú, ẹni tí ó yá a kò ní san ẹ̀san pada. Bí ó bá jẹ́ pé owó ni wọ́n fi yá ẹran náà lọ tí ó fi kú, a jẹ́ pé orí iṣẹ́ owó rẹ̀ ni ó kú sí.
16. “Bí ẹnìkan bá tan wundia tí kì í ṣe àfẹ́sọ́nà ẹnikẹ́ni, tí ó sì bá wundia náà lòpọ̀, ó gbọdọ̀ san owó orí rẹ̀ kí ó sì gbé e níyàwó.
17. Bí baba wundia náà bá kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ní fi ọmọ òun fún un, yóo san iye owó tí wọ́n bá ń san ní owó orí wundia tí kò mọ ọkunrin.
18. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí àjẹ́ wà láàyè.
19. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀, pípa ni kí wọ́n pa á.
20. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá rúbọ sí oriṣa-koriṣa kan lẹ́yìn OLUWA, píparun ni kí wọ́n pa á run.
21. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú tabi kí ó ni ín lára, nítorí pé ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti.
22. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ fìyà jẹ opó tabi aláìníbaba.
23. Bí ẹnikẹ́ni bá fìyà jẹ wọ́n, tí wọ́n bá ké pè mí, dájúdájú n óo gbọ́ igbe wọn;