Ẹkisodu 21:11-22 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Bí olówó ẹrubinrin yìí bá kọ̀, tí kò ṣe àwọn nǹkan mẹtẹẹta náà fún ẹrubinrin rẹ̀, ẹrubinrin náà lẹ́tọ̀ọ́ láti jáde ní ilé rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìsan ohunkohun.

12. “Bí ẹnikẹ́ni bá lu eniyan pa, pípa ni a óo pa òun náà.

13. Ṣugbọn bí olúwarẹ̀ kò bá mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó jẹ́ pé ó ṣèèṣì ni, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ibìkan tí n óo yàn fún yín.

14. Ṣugbọn bí ẹnìkan bá mọ̀ọ́nmọ̀ bá ẹlòmíràn jà, tí ó sì fi ọgbọ́n àrékérekè pa á, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sálọ sí ibi pẹpẹ mi, fífà ni kí ẹ fà á kúrò níbi pẹpẹ náà kí ẹ sì pa á.

15. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa òun náà.

16. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jí eniyan gbé, kì báà jẹ́ pé ó ti tà á, tabi kí wọ́n ká a mọ́ ọn lọ́wọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.

17. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé baba tabi ìyá rẹ̀ ṣépè, pípa ni kí wọ́n pa á.

18. “Bí eniyan meji bá ń jà, tí ọ̀kan bá fi òkúta tabi ẹ̀ṣẹ́ lu ekeji, tí ẹni tí wọ́n lù náà kò bá kú, ṣugbọn tí ó farapa,

19. bí ẹni tí wọ́n lù tí ó farapa náà bá dìde, tí ó sì ń fi ọ̀pá rìn kiri, ẹni tí ó lù ú bọ́ lọ́wọ́ ikú, ṣugbọn dandan ni kí ó san owó fún àkókò tí ẹni tí ó lù náà lò ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, kí ó sì ṣe ètò ìtọ́jú rẹ̀ títí yóo fi sàn.

20. “Bí ẹnìkan bá lu ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ ní kùmọ̀, tí ẹrú náà bá kú mọ́ ọn lọ́wọ́, olúwarẹ̀ yóo jìyà.

21. Ṣugbọn bí ẹrú náà bá gbé odidi ọjọ́ kan tabi meji kí ó tó kú, kí ẹnikẹ́ni má jẹ olówó ẹrú náà níyà, nítorí òun ni ó ni owó tí ó fi rà á.

22. “Bí àwọn eniyan bá ń jà, tí wọ́n sì ṣe aboyún léṣe, tóbẹ́ẹ̀ tí oyún rẹ̀ bàjẹ́ mọ́ ọn lára, ṣugbọn tí òun gan-an kò kú, ẹni tí ó ṣe aboyún náà léṣe níláti san iyekíye tí ọkọ rẹ̀ bá sọ pé òun yóo gbà bí owó ìtanràn, tí onídàájọ́ bá ti fi ọwọ́ sí i.

Ẹkisodu 21